explain-icon

Àlàyé

Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ fún wa pe ẹni ti o ni ọlá ju ninu awọn Mùsùlùmí ti o si tun ga ju ni ipo ni ọdọ Ọlọhun ni: Ẹni ti o ba kọ́ Kuraani, ni kika ati hiha, ati kike e ni pẹlẹpẹlẹ, ati agbọye rẹ, ati itumọ rẹ, ti o tun wa kọ́ ẹlòmíràn ni ohun ti n bẹ lọdọ rẹ ninu imọ Kuraani pẹlu lílò ó.

explain-icon

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  • Àlàyé iyì Kuraani, ati pe oun ni ọ̀rọ̀ ti o loore ju; tori pe ọ̀rọ̀ Ọlọhun ni.
  • Ẹni tí ó ni oore ju ninu awọn akẹ́kọ̀ọ́ ni ẹni tí n kọ́ ẹlòmíràn, kii ṣe ẹni tí ó fi mọ lori ara rẹ nìkan.
  • Kíkọ́ Kuraani, ati kikọ ẹlòmíràn ni Kuraani kó kike e ati awọn ìtumọ̀, ati awọn idajọ sinu.