?Ẹni ti o ba ka harafi kan ninu tira Ọlọhun, o maa fi gba ẹsan daada kan, ati pe ẹsan kan yio maa ni ilọpo mẹwaa iru rẹ

Lati ọdọ Abdullāh ọmọ Mas‘ūd – ki Ọlọhun yọnu si i – o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – sọ pe: «Ẹni ti o ba ka harafi kan ninu tira Ọlọhun, o maa fi gba ẹsan daada kan, ati pe ẹsan kan yio maa ni ilọpo mẹwaa iru rẹ, mi o sọ wipe “alif lām mīm” harafi kan ni o, amọ alifu harafi kan ni, lāmu naa harafi kan ni, mīmu naa harafi kan ni».
O ni alaafia - Tirmiziy ni o gba a wa

Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – sọ wípé dajudaju gbogbo Musulumi kọọkan ti o ba n ka harafi kan ninu tira Ọlọhun ni ẹsan kọọkan a máa bẹ fun un, ti wọn yio si ṣe adipele ẹsan naa fun un ni ilọpo mẹwaa iru rẹ. Lẹyin naa ni o wa ṣalaye pẹlu gbolohun rẹ ti o sọ pe: (Mi o sọ wipe “alif lām mīm” harafi kan ni o, amọ alif harafi kan ni, lām naa harafi kan ni, mīm naa harafi kan ni): Nítorí naa yio jẹ harafi mẹta ti o ko ẹsan ọgbọn sinu.

  1. Ṣiṣenilojukokoro lori pipọ ni kika Alukurāni.
  2. O n bẹ fun oluka nibi gbogbo harafi kọọkan ninu gbolohun ti o ba n ka ẹsan kan ti wọn o ṣe adipele rẹ ni ọna mẹwaa iru rẹ.
  3. Gbígbòòrò ikẹ Ọlọhun ati ọrẹ Rẹ latari pe O ṣe adipele ẹsan fun àwọn ẹrú Rẹ ni ti ọla ati ọrẹ lati ọdọ Rẹ.
  4. Ọla ti n bẹ fun Alukurāni lori ọrọ ti o yatọ si i, ati jijọsin pẹlu kika a, ìyẹn ri bẹẹ nitori pe ọrọ Ọlọhun ti O ga ni.

Ifiranṣẹ naa lọ pẹlu irọwọrọsẹ