Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe dajudaju Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- sọ ninu hadiiisi Qudusiy pe: Mo pin Suratul Fatiha lori irun laaarin Mi ati ẹru Mi si meji ọgbọọgba, idaji fun mi, ati idaji fun un. Idaji rẹ akọkọ je: Ọpẹ ati ẹyin ati gbigbe titobi fun Ọlọhun, wọn maa san an ni eyi ti o daa ninu ẹsan lori rẹ. Idaji rẹ keji jẹ: Idirẹbẹẹ ati àdúrà, Mo maa gba a Mo si maa fun un ni nnkan ti o beere. Ti Olukirun ba sọ pe: (Alhamdu lillaahi Rabbil ‘aalameen) Ọlọhun maa sọ pé: Ẹru Mi dupẹ fun Mi, ti o ba sọ pe: (Ar-Rahmaanir-Raheem), Ọlọhun maa sọ pé: Ẹru Mi yin Mi o si jẹwọ kikari idẹra Mi lori ẹda Mi, ti o ba wa sọ pe: (Maaliki Yawmid-Deen), Ọlọhun maa sọ pé: Ẹru Mi gbe Mi tobi, o si jẹ iyi ti o gbòòrò. Ti o ba sọ pe: (Iyyaaka na’budu wa lyyaaka nasta’een), Ọlọhun maa sọ pe: Eleyii wa laaarin Mi ati ẹru Mi. Idaji akọkọ ninu awọn ayah yii jẹ ti Ọlọhun, Oun naa ni: (Iyyaaka na’budu) oun ni ijẹwọ pe Ọlọhun ni O ni ẹtọ si ìjọsìn, ati idahun pẹlu ijọsin, ati pe pẹlu rẹ ni idaji ti o jẹ ti Ọlọhun fi wa si opin. Ati pe idaji keji ninu ayah naa, oun ni ti ẹru: (lyyaaka nasta’een) wiwa iranlọwọ lati ọdọ Ọlọhun, ati ṣiṣe adehun Rẹ pẹlu ṣíṣe iranlọwọ. Ti o ba wa sọ pe: (Ihdinas-Siraatal-Mustaqeem * Siraatal-lazeena an’amta ‘alaihim ghayril-maghdoobi ‘alaihim wa lad-daaalleen), Ọlọhun maa sọ pé: Eleyii jẹ idirẹbẹẹ ati adura lati ọdọ ẹru Mi, ati pe nnkan ti ẹru Mi ba beere, o maa jẹ tirẹ, dajudaju Mo ti gba adura rẹ.