Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- bi Ubay ọmọ Kahb léèrè nipa aaya ti o tobi ju ninu tira Ọlọhun, o wa ṣe iyèméjì nibi dáhùn, lẹ́yìn náà ni o wa sọ pé: Oun ni aayatul Kursiyy: {Allāhu, kò sí ọlọ́hun kan tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Òun, Alààyè, Alámòjúútó-ẹ̀dá}, Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa ṣe atilẹyin fun un, Anọbi wa lu u ni àyà lati tọka si pe o kún fun imọ ati ọgbọ́n, o wa ṣe adua fun un pe ki o maa dunnu pẹ̀lú imọ yii ki o si rọrùn fún un.