Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n ṣàlàyé pe dajudaju ninu awọn ami sisunmọ asiko igbende ni ki wọn ka imọ sharia kuro nilẹ, ati pe ìyẹn maa ri bẹẹ pẹlu iku awọn onimimọ, Ati pe esi ìyẹn ni pe ki aimọkan pọ ki o si fọnka, ki ṣina ati iwa aburu maa fọnka, ati ki mimu ọti pọ̀, onka awọn ọkunrin sì maa kere, ti onka obinrin si maa pọ titi ti o fi maa di pe ọkùnrin kan ni yoo maa bẹ fun aadọta obinrin ti yoo maa mójú tó awọn alamọri wọn ati awọn anfaani wọn.