Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe awọn eniyan kan maa han ni igbẹyin ìjọ rẹ ti wọn maa maa da adapa-irọ, ti wọn maa maa sọ nnkan ti ẹnikẹni ko sọ ṣíwájú wọn, ti wọn maa maa sọrọ pẹlu awọn hadiisi irọ ati agbelẹrọ, Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla maa ba a- pa wa láṣẹ lati jina si wọn ki a si ma jokoo pẹlu wọn, ki a si ma tẹti si awọn hadiisi wọn; ki hadiisi ti wọn hun yii ma baa duro ninu awọn ẹ̀mí, ki a ma baa kagara kuro nibi lila kuro nibẹ.