Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe dajudaju ninu awọn ami ọjọ igbende ti o tobi julọ ni ki oòrùn yọ lati ibuwọ rẹ dipo ki o yọ lati ibuyọ, ati pe igba ti awọn eniyan ba ri i, wọn maa gbagbọ lapapọ, Nigba yẹn igbagbọ alaigbagbọ ko nii ṣe e ni anfaani, iṣẹ rere tabi ironupiwada ko nii ṣe anfaani. Lẹyin naa Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe dajudaju ọjọ igbende maa de lojiji; o maa tó ti awọn eniyan sì maa wa lori awọn iṣesi wọn ati lori awọn eto igbesi aye wọn; Ọjọ igbende maa de ti olutaja ati oluraja ti maa tẹ aṣọ wọn laaarin wọn ti wọn ko si nii le ta a fun ara wọn ti wọn ko si tun nii le ka a, Ọjọ igbende maa de ti ọmọniyan si ti bu wara rakunmi rẹ ti o ni wàrà tó pọ̀, ko si nii mu u, Ọjọ igbende maa de ti ọmọniyan si n tun àmù omi rẹ ṣe ti o si tun n fi amọ rẹ́ ẹ, ti ko si nii le fun awọn ẹran ọ̀sìn rẹ ni omi mu nínú ẹ, Ọjọ igbende maa de ti ọmọniyan si ti maa gbe okele rẹ de ẹnu rẹ lati jẹ ẹ ti ko si nii jẹ ẹ.