Lati ọdọ Al-Miqdam Bin Ma’dikarib- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe: "Ẹ tẹti ẹ gbọ, o ṣee ṣe ki arakunrin kan, ki hadisi nipa mi de etigbọọ rẹ ti o si rọgbọku ni ori ibusun rẹ, ki o wa maa sọ pe: Iwe Ọlọhun n bẹ laaarin wa ati yin, nǹkan ti a ba ri nibẹ ni ẹtọ a maa ṣe e ni ẹtọ, nnkan ti a ba si ri nibẹ ni eewọ a maa ṣe e ni eewọ. Ati pe dajudaju nnkan ti Òjíṣẹ́ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ba ṣe ni eewọ da gẹgẹ bii nnkan ti Ọlọhun ṣe ni eewọ". O ni alaafia - Abu Daud ati Tirmiziy ati Ibnu Maajah ni wọn gba a wa
explain-icon

Àlàyé

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe asiko kan ti sunmọ ti iran kan ninu awọn eniyan o jẹ ẹni ti o jokoo nibẹ, ọkan ninu wọn maa rọgbọku ni ori ibusun rẹ, ti hadisi lati ọdọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- maa de eti igbọ rẹ, yoo waa maa sọ pe: Nnkan ti o maa ṣe ìyàtọ̀ laaarin wa ati laaarin yin nibi awọn alamọri ni Kuraani Alapọn-ọnle, o si ti to wa, nnkan ti a ba ba nibẹ ninu nnkan ẹtọ a maa ṣiṣẹ pẹlu rẹ, nnkan ti a ba si ba nibẹ ninu nnkan eewọ a maa jina si i. Lẹyin naa Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣàlàyé pe gbogbo nnkan ti o ṣe ni eewọ tabi kọ kuro nibẹ ninu sunnah rẹ, ninu idajọ o da gẹgẹ bii nnkan ti Ọlọhun ṣe ni eewọ ninu iwe Rẹ; nitori pe oun ni o n jiṣẹ Oluwa rẹ.

explain-icon

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  • Gbigbe sunnah tobi gẹgẹ bi wọn ṣe maa n gbe Kuraani tobi ti wọn si maa n ṣe iṣẹ́ pẹlu rẹ.
  • Itẹle Òjíṣẹ́ ni itẹle ti Ọlọhun, iyapa rẹ naa si jẹ ìyapa Ọlọhun ti ọla Rẹ ga.
  • Ẹri to fẹsẹrinlẹ ni Sunnah ati fifesi fun awọn ti wọn kọ Sunnah tabi ti wọn tako o.
  • Ẹni ti o ba gunri kuro nibi sunnah ti o so pe Kuraani nìkan ti to, o ti gunri kuro nibi mejeeji lapapọ, o si tun jẹ opurọ nibi apemọra itẹle Kuraani rẹ.
  • Ninu awọn ẹri ijẹ-anabi rẹ- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ni àwọn nǹkan tí ó sọ pé ó máa ṣẹlẹ̀ ni ọjọ́ iwájú, ti o si ṣẹlẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ṣe wí.