explain-icon

Àlàyé

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣàlàyé pe dajudaju ẹni ti o ba mọọmọ parọ mọ ọn, pẹlu fifi ọrọ kan tabi iṣẹ kan ti si ọdọ rẹ ni ti irọ, dajudaju ibujokoo kan n bẹ fun un ni ọrun ninu ina; ki o maa jẹ ẹsan fun un lori pipa irọ mọ ọn.

explain-icon

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  • Irọ pipa mọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ni ti mimọọmọ jẹ okunfa wiwọ ina.
  • Pipa irọ mọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ko da gẹgẹ bii irọ pipa mọ awọn eniyan yoku, fun nnkan ti o maa jẹ jáde latara ìyẹn ninu awọn ibajẹ ti wọn tobi ninu ẹsin ati ayé.
  • Ikilọ kuro nibi fifọn awọn hadiisi ka ṣíwájú ifirinlẹ ati amọdaju ninu nini alaafia ṣíṣe afiti rẹ sọ́dọ̀ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-.