Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n ṣọ wa lara kúrò nibi itẹsiwaju ninu abosi dídá ẹṣẹ ati ṣíṣe ẹbọ, ati ṣíṣe abosi fun awọn èèyàn nibi ẹ̀tọ́ wọn; torí pé Ọlọhun maa n lọ alabosi lára, O si maa n jẹ ki ẹmi rẹ o gùn ti dúkìá rẹ si tun maa pọ̀, ko waa ni kanju fi ìyà jẹ ẹ, ti ko ba wa ronupiwada, O maa mu u ti ko si nii fi i sílẹ̀ fun abosi rẹ ti o pọ. Lẹ́yìn naa ni Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa ka: {Báyẹn ni ìgbámú Olúwa rẹ. Nígbà tí Ó bá gbá àwọn ìlú alábòsí mú, dájúdájú Ó máa gbá a mú pẹ̀lú ìyà ẹlẹ́ta-eléro t’ó le} [Huud: 102].