Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣekilọ kuro nibi abosi, ninu rẹ ni: Ṣíṣe abosi awọn eniyan ati abosi ara ẹni ati ṣíṣe abosi nibi iwọ Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga-, Oun ni gbigbe funfun ẹni ti o ni ẹtọ ni ẹtọ rẹ ju silẹ, ati pe ṣíṣe abosi jẹ okunkun fun awọn ti wọn n ṣe e ni ọjọ igbedide latara ṣiṣẹlẹ awọn ile koko ati awọn ibẹru, O tun kọ kuro nibi ash-shuhhu, oun ni eyi ti o le koko ninu ahun pẹlu ojúkòkòrò, ninu rẹ ni aṣeeto nibi pipe awọn iwọ ti owo ati ilekoko ojúkòkòrò lori aye, Ati pe iran yii ninu abosi ti pa awọn ti wọn ṣíwájú wa run ninu awọn ijọ, nigba ti o ti wọn lọ sibi pipa awọn kan ninu wọn, ati ṣíṣe nnkan ti Ọlọhun ṣe leewọ ninu awọn nnkan eewọ lẹtọọ.