Lati ọdọ Abu Sa‘eed Al-Khuduriy - ki Ọlọhun yọnu si i - dajudaju ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe: «Ọkunrin o gbọdọ maa wo ihoho ọkunrin, obinrin naa o si gbọdọ maa wo ihoho obinrin, ọkunrin o si gbọdọ maa wa ni ihoho pẹlu ọkunrin ninu asọ kan, obinrin naa o si gbọdọ maa wa ni ihoho pẹlu obinrin ninu asọ kan». O ni alaafia - Muslim gba a wa
explain-icon

Àlàyé

Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - kọ ki ọkunrin o maa wo ihoho ọkunrin, tabi ki obinrin o maa wo ihoho obinrin. Ati pe nkan ti n jẹ ‘Aorah ni: Gbogbo nkan ti wọn maa n tiju latara rẹ ti o ba hàn (nkan ti wọn o ki n fẹ ki o han), ati pe ihoho ọkunrin ni nkan ti o wa laarin idodo rẹ ati orunkun rẹ, Ati pe gbogbo ara obinrin pata ni ihoho fun awọn ọkunrin ajoji, ṣugbọn fun awọn obinrin ati awọn eleewọ rẹ, o le fi han nkan ti o saaba maa n han nigba ti o ba n ṣiṣẹ ni inu ile. Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - tun kọ kuro nibi ki ọkùnrin ati ọkùnrin o wa ni ihoho ninu asọ kan tabi lábẹ́ aṣọ ibora kan, ati nibi ki obinrin ati obinrin o wa ni ihoho ninu aṣọ kan tabi lábẹ́ aṣọ ibora kan; nítorí pé ìyẹn le maa fa ki ọkọọkan ninu wọn o maa fi ọwọ pa ihoho ẹnìkejì rẹ, ati pe fifi ọwọ kan an (ihoho) nkan ti wọn kọ ni gẹgẹ bii wiwo o naa ni, koda kikọ rẹ (fifi ọwọ pa ihoho) tun le jù; latari pe ìyẹn le tini lọ sibi awọn ibajẹ ti o tobi.

explain-icon

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  • Kikọ kuro nibi wiwo awọn ihoho yatọ si ọkọ ati iyawo rẹ.
  • Isilaamu ṣẹni lojukokoro lori fifọ awujọ mọ ati titi ilẹkun awọn ọna ti o le ja si ibi awọn ibajẹ.
  • Ṣiṣe lẹtọọ wiwo ihoho nigba ti bukaata ba pepe fun un gẹgẹ bii ṣiṣe ìwòsàn ati nkan ti o jọ ọ, pẹlu pe ki o jẹ èyí tí ko si adun nibẹ.
  • Wọn pa musulumi l'aṣẹ pẹlu bibo ihoho rẹ ati rírẹ oju rẹ nilẹ kuro nibi ihoho ẹlòmíràn.
  • Wọn s'ẹsa kikọ fún ọkunrin pẹlu ọkunrin ati obinrin pẹlu obinrin; nítorí pé o yara pepe lọ si'bi wiwo ati ṣiṣi awọn ihoho silẹ.