Ojiṣẹ Ọlọhun, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a, n paṣẹ fún àwọn ijọ rẹ̀ pé kí wọ́n jinna sí awọn iwa ọdaran ati ẹṣẹ meje ti n pani run, nigba ti wọ́n wá bi i leere pé kí ni wọ́n? O ṣalaye pé àwọn ni: Ikinni: Ṣíṣe ẹbọ pẹlu Ọlọhun, nipasẹ wíwá alafiwe ati alafijọ fun Un, èyí ó wù ki o jẹ, mimọ ni fún Ọlọhun, ati ṣiṣe eyikeyii ninu awọn ijọsin fún ẹlomiran tó yatọ si Ọlọhun Allah, Ọba Aleke ọla. Àti pé Ojiṣẹ Ọlọhun – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – bẹrẹ pẹlu ẹbọ; nitori pe oun ló tobi julọ ninu awọn ẹṣẹ. Ikeji: Idán ṣíṣe – oun naa ni títa kókó àwọn nkankan, ati pípọfọ̀, ati awọn oogùn, ati awọn èéfín ti n rú jáde – yoo lapa lára ẹni tí wọ́n bá ṣe idan sí, bii kí o pa ẹni naa, tabi kí ó kó àisàn ba a, tabi kí ó fa ipinya laarin ọkọ ati aya. Iṣẹ ẹ̀ṣù ni, ati pé wọn ò lè rí ọpọlọpọ ninu awọn idan yi ṣe ayafi nipasẹ ẹbọ ati ìpèsè nkan ti awọn ẹ̀mí eṣu buruku nífẹ̀ẹ́ si fun wọn. Ẹkẹta: Pípa ẹmi ti Ọlọhun ṣe ni eewọ lati pa a ayafi pẹ̀lú nǹkan ti o maa sọ ọ́ di ẹ̀tọ́ ti o ba ṣẹria mu ti oludajọ ṣẹria sì maa mu u ṣẹ. Ẹkẹrin: Gbígba owo èlé lati lè jẹ́ ẹ tabi lilo o ní ọna miiran ninu awọn ọna anfaani. Ìkarùn-ún: Ìtayọ àlà sí owó ọmọ kékeré tí bàbá rẹ̀ kú nígbà tí kò ì tíì bàlágà. Ẹkẹfa: Sísá kúrò loju ogun ẹsin pẹ̀lú awọn keferi. Ìkeje: Fífi ẹ̀sùn àgbèrè kan àwọn obìnrin olómìnira, oluṣọra nibi ìranù, àti fífi ẹ̀sùn kan àwọn ọkùnrin bakan naa.