Arakunrin meji njà lọdọ Anọbi (ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ máa ba a), bẹẹ ni oju ọkan ninu awọn mejeeji ti pọ́n koko, bẹẹ ni isan to yipo ọrun rẹ ti ran jáde. Ni ojisẹ Ọlọhun (ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ máa ba a) bá sọ pé: Dajudaju emi mọ gbólóhùn kan ti ẹni to nbinu yii bá wí i, ibinu naa yóò sa kuro fun, ti o ba le sọ pé: mo sa di Ọlọhun nibi aburu èṣù (Satani) ẹni ẹkọ ẹni egbe. Wọ́n sọ fun un pe: Dajudaju Anọbi (ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ máa ba a) sọ pe: Wá isọra pẹlu Ọlọhun nipa èṣù (Satani). Ni o ba dahun, o ni: se were ni mi bi?! o le ro pe ẹnikan kò nii wá isọra nipa èṣù (Satani) ayáafi ẹni tí o ba ya were.