Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - kọja nibi saare meji kan, ni o wa sọ pe: Dajudaju awọn meji ti wọn ni saare mejeeji yii wọn n jẹ wọn niya lọwọ; ati pe wọn o jẹ wọn niya lori alamọri ti o tobi ni iwoyesi yin, bi o tilẹ̀ jẹ́ pé o tobi lọdọ Ọlọhun, Ẹ o wa ri ọkan ninu awọn mejeeji o jẹ ẹni ti ko ni akolekan nipa ṣiṣọ ara rẹ ati aṣọ rẹ kuro nibi itọ nigba ti o ba n gbọ bukaata rẹ, Ati pe ikeji maa n ṣe ofofo laarin awọn eeyan, ti yio wa maa gbe ọrọ ẹni ti o yatọ si i ni erongba ifi-ara-ni ati dida iyapa ati ogun silẹ laarin awọn eeyan.