Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pé Ọlọhun ti ọla Rẹ ga n koriira ninu awọn èèyàn ẹni ti o le ni àtakò ti o si maa n sáábà ṣe àtakò, ẹni tí kii tẹrí ba fun òdodo, ti o maa n gbìyànjú láti da a pada pẹlu iyàn jíjà rẹ, tabi ki o maa ṣe àtakò lori ododo, ṣùgbọ́n o maa ki aṣeju bọ̀ ọ́, o tun maa ṣe àtakò láìní imọ.