Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ṣe alaye pe dajudaju Ọlọhun ti ọla Rẹ ga maa n sọkalẹ ni gbogbo oru si sanmọ aye nigba ti o ba ku idamẹta igbẹyin ninu oru, O si tun n ṣe awọn ẹru Rẹ ni ojukokoro ki wọn o pe E, pe Oun yio jẹ ipe ẹni ti o ba pe Oun, O si tun ṣe wọn ni oju ọyin ki wọn o bi I leere nkan ti wọn n fẹ, pe Oun yio fun ẹni ti o ba bi Oun leere, O si tun pe wọn sibi ki wọn wa aforijin Rẹ nibi awọn ẹṣẹ wọn pe Oun maa n ṣe aforijin fun awọn ẹru Oun ti wọn jẹ olugbagbọ ododo.