Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n ṣàlàyé titobi ọla Ọlọhun lori awọn olugbagbọ, ati ṣíṣe deedee Rẹ pẹlu awọn alaigbagbọ. Ṣugbọn olugbagbọ, ẹsan daadaa ti o ba ṣe ko nii dínkù; bi ko ṣe pe wọn maa fun un ni dáadáa pẹlu rẹ ni aye lori itẹle rẹ, pẹlu nnkan ti wọn maa fi pamọ fun un ninu ẹsan ni ọrun; wọn si le tọju gbogbo ẹsan naa fun un ni ọrun. Ṣugbọn alaigbagbọ, Ọlọhun maa fun un ni ẹsan nnkan ti o ba ṣe ninu awọn daadaa pẹlu awọn daadaa aye, ti o ba ti wa de ọrun, ko nii si ẹsan kan ti wọn yoo san an lẹsan rẹ; nitori pe iṣẹ rere ti yoo ṣeni ni anfaani ni aye ati ọrun dandan ni ki ẹni ti o ṣe e jẹ olugbagbọ.