Arakunrin kan ninu awọn ara Najd wa sọ́dọ̀ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ti irun rẹ ri wuruwuru, ti ohun rẹ lọ sókè, ti wọn ko gbọ nnkan ti o n sọ ye, titi o fi sunmọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-, ti o si beere nipa awọn ọran-anyan Isilaamu? Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- bẹ̀rẹ̀ pẹlu irun, ti o si sọ fun un pe dajudaju Ọlọhun ṣe irun marun-un ni ọran-anyan le e lori ni gbogbo ọ̀sán ati oru. O sọ pe: Njẹ nnkan kan tun jẹ dandan fun mi ninu awọn irun yàtọ̀ si awọn marun-un yii? O sọ pe: Rara, afi ti o ba ki nafila lati ṣe aṣegbọrẹ. Lẹyin naa, Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: Ninu nnkan ti Ọlọhun tun ṣe e ni dandan le ẹ lori ni awẹ oṣu Ramadan. O sọ pe: Njẹ nnkan kan tun jẹ dandan fun mi ninu awẹ yàtọ̀ si awẹ Ramadan? O sọ pe: Rara, afi ti o ba gba aawẹ fun aṣegbọrẹ. Lẹyin naa, Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- dárúkọ saka fun un. Arakunrin naa sọ pe: Njẹ nnkan kan tun jẹ dandan fun mi ninu awọn saara lẹyin saka ọran-anyan? O sọ pe: Rara, a fi ti o ba ṣe aṣegbọrẹ. Lẹyin igba ti arakunrin naa gbọ́ lati ọdọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- nipa awọn ọran-anyan yìí, o pẹyin da, o si búra pẹlu Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- pe oun maa dunni mọ́ ọn laisi alekun tabi adinku, ni Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ lẹyin ìyẹn pé: Ti arakunrin naa ba sọ ododo lori nnkan ti o bura le lori dajudaju o maa wa ninu awọn olujere.