Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - fi Isilaamu jọ ile kan ti wọn mọ daadaa pẹlu origun maarun ti o gbe ile naa duro, ti awọn iwa Isilaamu ti o sẹku jẹ pipari ile naa. Akọkọ awọn origun yii ni: Ijẹrii mejeeji; ijẹrii pe ko si ẹni ti ijọsin ododo tọ si ayaafi Allāhu, ati pe dajudaju Muhammad ojiṣẹ Rẹ ni, ati pe origun kan ni mejeeji; ti ọkan o lee ja kuro lara ìkejì, ẹru o sọ mejeeji ni ẹni ti n fi ijẹ ọkan ṣoṣo Ọlọhun ati lilẹtọọ Rẹ si ijọsin ni Oun nikan ṣoṣo laisi ẹlòmíràn yatọ si i rinlẹ, ti yio si maa ṣiṣẹ tọ awọn nkan ti o n tọka si, ki o si tun gba iransẹ Muhammad - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - gbọ ni ẹni ti yio maa tẹle e. Origun keji ni: Gbigbe irun duro, oun naa ni awọn irun ọranyan marun-un ni ojumọ kan ati oru kan: Alufajari, ati Àílà, ati Alaasari, ati Magribi, ati Ishai, pẹlu awọn majẹmu wọn ati awọn origun wọn ati awọn ọranyan wọn. Origun kẹta ni: Yiyọ zakah ọranyan, oun naa ni ijọsin owo ti o jẹ dandan nibi gbogbo dukia ti o ba ti to odiwọn ti wọn fi aala si ninu shariah, ti wọn o fun awọn ti wọn ni ẹtọ si i. Origun kẹrin ni: Hajji, oun naa ni gbigbero Makkah lati gbe awọn iṣẹ ìjọsìn duro, ni ti jijọsin fun Ọlọhun ti O biyi ti O gbọnngbọn. Origun karun-un ni: Aawẹ Ramadan, oun naa ni kikoraro nibi jijẹ ati mimu ati nkan ti o yatọ si mejeeji ninu awọn nkan ti o le ba aawẹ jẹ pẹlu aniyan jijọsin fun Ọlọhun, lati igba ti alufajari ba ti yọ titi ti oorun yio fi wọ.