Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - n fun wa ni iro pe dajudaju ẹni ti o ba sọ gbolohun mimu Ọlọhun lọkan (Laa illaha illā Allāhu) l'ẹni ti o mọ itumọ rẹ ti o si n ṣiṣẹ tọ nkan ti o n pepe si, ti o si tun jẹrii si jijẹ ẹrusin Muhammad - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ati ijẹ ojiṣẹ rẹ, tí o si tun fi jíjẹ́ ẹrusin ati jijẹ ojiṣẹ Isa rinlẹ, Àti pé dajudaju Ọlọhun da a pẹlu gbolohun Rẹ pe "kun" (jẹ bẹ́ẹ̀) ti o si jẹ bẹ́ẹ̀, ati pe o jẹ ẹmi kan ninu awọn ẹmi ti Ọlọhun da, ti o si tun fọ iya rẹ mọ kuro nibi nkan ti awọn Yahudi fi ti si i lọdọ, Ti o si tun ni igbagbọ pe dajudaju al-jannah ododo ni, ati pe ina ododo ni, lẹniti o ni adisọkan bíbẹ mejeeji, ati pe dajudaju awọn mejeeji idẹra Ọlọhun ati ijiya Rẹ ni, Ti o si ku lori iyẹn; nitori naa ibudesi rẹ ni Aljannah koda ki o jẹ alaseeto nibi itẹle, ti awọn ẹṣẹ si n bẹ fun un.