explain-icon

Àlàyé

Àwọn ìjọ kan ninu awọn saabe Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa, wọn si bi i leere nipa nnkan ti wọn n ri ninu ẹ̀mí wọn ninu awọn alamọri nla ti sisọ rẹ tobi latara biburu rẹ ati sisa wọn fun un, O sọ- Ki ikẹ Ọlọhun ati ọla maa ba a- pe: Dajudaju eyi ti ẹ ri ni igbagbọ òdodo ti ko ruju ati àmọ̀dájú ti o maa jẹ ki ẹ le kọ ohun ti èṣù n jù sinu ọkàn, ati kikọ wiwi i jade lẹ́nu, ati titobi ìyẹn ninu ẹ̀mí yin, ati pe èṣù ko ráyè ninu ọkàn yin, yatọ si ẹni ti èṣù ráyè ninu ọkan rẹ, ti ko si lee da a padà.

explain-icon

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  • Alaye lilẹ èṣù pẹlu awọn oni igbagbọ nipa pe ko kapa nnkankan afi royiroyi.
  • Aigbagbọ ati aigbawọle nnkan ti o n sọ sinu ẹ̀mí ninu awọn royiroyi; nitori pe o wa lati ọdọ èṣù.
  • Royiroyi èṣù ko lee ni olugbagbọ lara, sugbọn ki o maa wa iṣọra pẹlu Ọlọhun kuro nibi royiroyi rẹ, ki o si jawọ kuro nibi itẹsiwaju nibi ìyẹn.
  • Didakẹ ko lẹtọọ fun Mùsùlùmí nipa nnkan ti o ba rú u lójú ninu alamọri ẹsin rẹ, o lẹtọọ fun un lati beere nipa rẹ.