Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọrọ nipa iwosan ti o ṣe anfaani fun awọn ibeere ti èṣù fi n ko royiroyi ba olugbagbọ, Èṣù o maa sọ pé: Ta ni o ṣẹda eyi? Ta ni o ṣẹda eyi? Ta ni o ṣẹda sanmọ? Ta ni o ṣẹda ilẹ? Olugbagbọ yoo da a lohun ni ti ẹsin ati ti adamọ ati ti laakaye pẹlu ọrọ rẹ pé: Ọlọhun ni, Ṣùgbọ́n èṣù ko nii duro sibi aala yii ninu awọn royiroyi, bi ko ṣe pe yoo kúrò nibẹ titi yoo fi sọ pé: Ta ni o ṣẹda Oluwa rẹ? Nibi ìyẹn ni olugbagbọ ti maa da awọn royiroyi yii padà pẹlu awọn alamọri mẹta kan: Nini igbagbọ ninu Ọlọhun. Wiwa isọra pẹlu Ọlọhun kuro lọdọ èṣù. Kiko ara ro nibi titẹsiwaju pẹlu awọn royiroyi.