Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- pàṣẹ pẹlu riranti Ọlọhun nigba wiwọ inu ile ati ṣíwájú jijẹ oúnjẹ, ti o ba ranti Ọlọhun pẹlu sisọ pe: (Bismillah) nigba ti o ba wọ inu ile rẹ ati ìbẹ̀rẹ̀ jijẹ oúnjẹ rẹ, Shaitan maa sọ fun awọn oluranlọwọ rẹ pé: Ko si ipin fun yin lati sun tabi lati jẹun alẹ ninu ile yii ti ẹni ti o ni i ti wa iṣọra kuro lọdọ yin pẹlu riranti Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga-. Ṣugbọn ti ọkùnrin ba wọ ile rẹ ti ko ranti Ọlọhun nigba ìwọlé rẹ tabi nigba jijẹ oúnjẹ rẹ, Shaitan maa sọ fun awọn oluranlọwọ rẹ pe wọn ti ri ibusun ati oúnjẹ alẹ ninu ile yii.