Anọbi (ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ máa ba) fún wa niro pe dájúdájú Ọlọhun ti ọla Rẹ ga sọ pé: Emi wà pẹlu aba ẹru mi sí mi, Emi yóò sì máa bá a lo nibamu aba rẹ sí mi, pẹlu ini ireti ati ifun ni ni ireti amojukuro, bẹẹni ma máa ṣe oore eyi ti nfọkan sí lọdọ mi, tabi awọn nkan mii; mo wà pẹlu rẹ pẹlu ikẹ ati ifini se kongẹ daada ati itọsọna ati amojuto ati ikun lọwọ nigbati o ba rántí mi. Ti o bá seranti mi ninu ọkan rẹ ni òun nìkan ti ẹnikankan kò si ni bẹ pẹlu sise afọmọ ati gbólóhùn pe kò sí Ọlọhun míràn to yẹ kaa maa sìn àyàafi Allah, tabi awọn ìrántí mii, maa rántí rẹ ninu ẹmi Mi. Ti o bá rántí Mi láàrin àwọn akojọ kan, Emi naa yóò rántí rẹ láárín awọn akojọ ti wọn pọ ti wọn si dáa jù wọn lọ. Ẹni tí o ba sun mọ Ọlọhun ni iwọn ina ika ọwọ mararun tan Ọlọrun yóò se alekun fun yóò wá sun mọ ni iwọn igunpa kan. Ti o bá sun mọ ni iwọn igunpa kan Ọlọhun yóò sún mọ ni iwọn ina apá mejeeji tan lẹ kan naa. Ti o ba wa bá Ọlọhun ni ẹnití nrin Ọlọhun yóò wá ba ni yara yara. Ti ẹru (eniyan) bá sun mọ Oluwa rẹ pẹlu imáa tẹle àṣẹ Rẹ ti o kọ ju sí daada, dajudaju Ọlọhun Oluwa ti O ga jù lọ yóò se alekun ni isunmọ rẹ pada yóò máa jẹ ẹsan iru nkan to se. Gbogbo igba ti ijẹ ẹru fún Ọlọhun ti olugbagbọ ba ti pé fún Oluwa rẹ náà ni Ọlohun ti Ọ̀la Rẹ ga yóò sún mọ, ọrẹ Ọlohun ati ẹsan Rẹ pọ jù iṣẹ ati wahala ti ẹru se lori rẹ lọ, eyi ti o ṣẹlẹ nipe ẹsan Ọ̀lọhun tẹwọn lori iṣẹ ẹru pẹlu ọna ati iye iṣẹ tó ṣe. Olugbagbọ ododo yóò máa daba daada sí Oluwa rẹ, yóò sì máa ṣiṣẹ daada, yóò sì máa yàrá sise daada, yóò sì máa ṣe alekun iṣẹ tí yóò fi pàdé Ọlọhun.