Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - funni niroo ninu hadīth qudusiy pe dajudaju Ọlọhun ti O biyi ti O gbọnngbọn sọ pe: Ẹni ti o ba fi suta kan aayo kan ninu awọn aayo Mi, ti o wa mu inu bi i, ti o tun korira rẹ, Mo ti fi mọ ọn Mo si ti kede ibasọta fun un. Ati pe aayo Ọlọhun ni: Mumini olupaya, ati pe lori odiwọn nkan ti n bẹ fun ẹru ni igbagbọ ati ipaya ni yio maa jẹ ipin rẹ nibi ijẹ aayo Ọlọhun. Ati pe musulumi o nii maa sunmọ Oluwa rẹ pẹlu nkankan ti yoo nífẹ̀ẹ́ si ju nnkan ti O ṣe ni ọranyan ti O si tun ṣe ni dandan lọ ninu ṣiṣe awọn nǹkan ti sharia pàṣẹ rẹ ati gbigbe awọn eewọ jusilẹ, ati pe musulumi o nii yẹ ko nii gbo lẹni ti yio maa sunmọ Oluwa rẹ pẹlu awọn aṣegbọrẹ mọ awọn ọranyan; titi ti ọwọ rẹ o fi tẹ ifẹ Ọlọhun. Ti Ọlọhun ba ti wa nífẹ̀ẹ́ rẹ, Ọlọhun ni yio maa tọ́ ọ sọ́nà nibi awọn oríkèé ara mẹrẹẹrin yii: Yoo tọ́ ọ sọ́nà nibi igbọrọ rẹ, nitori naa ko nii gbọ́ nkankan ayaafi nkan ti yoo yọ Ọlọhun ninu. Yoo tọ́ ọ sọ́nà nibi iriran rẹ, nitori naa ko nii wo nkankan ayaafi nkan ti Ọlọhun nífẹ̀ẹ́ si wiwo o ti O si tun yọnu si i. Yoo tọ́ ọ sọ́nà nibi ọwọ rẹ, nítorí naa ko nii fi ọwọ rẹ ṣe nkankan ayaafi nkan ti yio yọ Ọlọhun ninu. Yoo tun tọ ọ sọ́nà nibi ẹsẹ rẹ, nitori naa ko nii maa rin ayaafi lọ sibi nkan ti yio yọ Ọlọhun ninu, ko si nii maa ṣe igbiyanju ayaafi sibi nkan ti oore wa nibẹ. Pẹlu eyi, ti o ba bi Ọlọhun leere nkankan dajudaju Ọlọhun O fun un ni nkan ti o beere, nitori naa yio jẹ ẹni ti adua rẹ o maa gba, ti o ba si tun wa iṣọra pẹlu Ọlọhun ti o tun sadi I lẹni ti n wa aabo, dajudaju Ọlọhun ti mimọ n bẹ fun Un O ṣọ ọ, yoo si tun da aabo bo o nibi nkan ti o n paya. Lẹyin naa ni Ọlọhun ti ọla Rẹ ga sọ pe: Mi o fa sẹyin nibi nkankan ti Mo fẹ ṣe bii ifasẹyin Mi nibi gbigba ẹmi Mumini ni ti ikaaanu rẹ; nítorí pé o korira iku latari inira ti o wa nibẹ, ati pe Ọlọhun si korira nkan ti yio maa ni mumini lara.