Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n ṣàlàyé ninu haiisi kudsiy pe Ọlọhun ti O lágbára ti O gbọnngbọn sọ nípa àwọn ọṣẹbọ ati awọn Kèfèrí pe wọn n pe Oun ni opurọ, wọn si n ròyìn Rẹ pẹlu abuku, ìyẹn ko si tọ fun wọn. Nipa pipe E ni opurọ ni: ero wọn pe Ọlọhun ko lee da wọn pada lẹyin iku wọn gẹgẹ bi O ṣe da wọn ni akọkọ lati ibi àìsí, O wa fesi fun wọn pe Ẹni ti O bẹrẹ dida ẹ̀dá lati ibi àìsí ni ikapa lati da wọn pada, koda oun ni o rọrùn jù, bi o ti lẹ je pe bákan náà ni mejeeji ṣe ri ni ọdọ Ọlọhun ati dida ati dida pada, Ọlọhun ni ikapa lórí gbogbo nnkan. Ni ti eebu wọn: oun ni ọrọ wọn pe: O ni ọmọ, O wa fesi fun wọn pe Ọkan ni Oun, Oun si da ni gbogbo pipe nibi awọn orukọ Rẹ ati awọn iroyin Rẹ, ati awọn iṣe Rẹ, O mọ kuro nibi gbogbo àléébù, Ajironukan ni ti ko bukaata si ẹni kankan, ti gbogbo èèyàn si n bukaata si I, ko bi ọmọ kankan, ko si jẹ ọmọ fun ẹni kankan, ko si si ẹni ti o jọ Ọ, mimọ ni fun Un.