Lati ọdọ Ibnu Abbaas (ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji) Lati ọdọ Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ninu nǹkan ti o gba wa lati ọdọ Oluwa rẹ ti O lágbára ti O gbọnngbọn, o sọ pé: “Dájúdájú Ọlọhun kọ daadaa ati aburu, lẹyin naa O ṣalaye ìyẹn, ẹni tí ó bá gbèrò dáadáa, ti ko wa ṣe e, Ọlọhun maa kọ ọ fun un ni ọdọ Rẹ ni dáadáa ti o pé, ti o ba wa gbero rẹ, ti o wa ṣe e, Ọlọhun maa kọ ọ fun un ni ọdọ Rẹ ni dáadáa mẹ́wàá titi de ìlọ́po ẹẹdẹgbẹrin, titi de ìlọ́po ti o pọ̀, ẹni ti o ba gbèrò aburu, ti ko wa ṣe e, Ọlọhun maa kọ ọ fun un ni ọdọ Rẹ ni dáadáa ti o pe, ti o ba wa gbero rẹ ti o si ṣe e, Ọlọhun maa kọ ọ fun un ni aburu ẹyọkan”. O ni alaafia - Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni
explain-icon

Àlàyé

Òjíṣẹ́ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n ṣàlàyé pe Ọlọhun ti kádàrá dáadáa ati aburú, lẹyin naa O ṣàlàyé fun awọn malaika méjèèjì bi wọn ṣe maa kọ ọ: Ẹni tí ó bá gbèrò ṣíṣe dáadáa, wọn maa kọ ọ fun un ni dáadáa ẹyọkan koda ki o ma ṣe e, ti o ba wa ṣe e, wọn maa ṣe adipele rẹ pẹlu ìlọ́po mẹ́wàá irú rẹ titi de ìlọ́po ẹẹdẹgbẹrin, titi de ìlọ́po ti o pọ, alekun naa maa wa ni ibamu si bi ọkàn ba ṣe ni imọkanga sí, ati bi àwọn èèyàn ba ṣe ṣe anfaani latara rẹ̀ si, ati ohun ti o jọ ìyẹn. Ẹni tí ó bá gbèrò lati ṣe aburu, lẹyin naa o wa gbe e ju silẹ, wọn maa kọ ọ fun ni dáadáa, ti ko ba wa raye ṣe e pẹlu pe ko ṣe àwọn okunfa rẹ, wọn ko nii kọ nǹkan kan, ti o ba gbe e ju silẹ ni ti ikagara, wọn maa kọ àníyàn rẹ fun un, ti o ba wa ṣe e, wọn maa kọ ọ fun un ni aburu ẹyọkan.

explain-icon

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  • Ṣiṣe àlàyé ọla Ọlọhun ti o tobi lori ijọ yii nibi adipele àwọn dáadáa ati kikọ wọn ni ọdọ Rẹ, ati àìsí adipele fun aburu.
  • Pataki aniyan ninu awọn iṣẹ ati oripa rẹ.
  • Ọlá Ọlọhun ati aanu Rẹ ati dáadáa Rẹ ni pe ẹni ti o ba gbèrò dáadáa ti ko wa ṣe e, Ọlọhun maa kọ ọ ni dáadáa.