Anọbi (ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ máa ba a) ṣe awọn ọmọlẹyìn loju kòkòrò (o fa ifẹ wọn) síbi imaa sisẹ, ati ki wọn si bẹrù Ọlọhun bi wọn ba se ni agbara mọ, láì ṣe àṣe kọja ààlà, ati láì ṣe asee to, ki wọn ni eero iṣẹ àṣe dara pẹlu imáa ṣe iṣẹ wọn nítorí ti Ọlọhun (aniyan tori Ọlọhun) ati imáa tẹlé ilana ati alaalẹ anọbi, ki iṣẹ wọn le jẹ àtéwọgbà, atipe ki o jẹ okunfa isọkalẹ àánu Ọlọhun fún wọn. O si tun fún wọn niro pe isẹ enikọọkan yin nikan ko lee gbayinla, sugbọn afi ki ẹ rí ikẹ gba lọdọ Ọlọhun. Wọn sọ pe: titi o fi de orí rẹ, irẹ ojisẹ Ọlọhun, iṣẹ rẹ ko lee gbaọla toun ti bi o se tobi to? Anọbi sọ pe: titi ofi dé orí mi, ayaafi ki Ọlọhun bomi lasiri pẹlu aanu Rẹ.