explain-icon

Àlàyé

Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pé Ọlọhun ti ọla Rẹ ga ko nii wo àwòrán ẹrú ati ara wọn, boya o rẹwà ni abi o burẹ́wà? Boya o tobi ni abi o kéré? Bóyá o ni alaafia ni abi o n ṣe àìsàn? Ko si nii wo dúkìá wọn, bóyá o pọ ni abi o kéré? Ọlọhun ti O lágbára ti O gbọnngbọn ko nii fi àwọn nǹkan wọ̀nyí bi àwọn ẹrú Rẹ, ko si nii ṣe ìṣirò wọn lórí rẹ ati bi wọn ṣe yatọ si ara wọn nínú ẹ, ṣùgbọ́n O maa wo ọkàn wọn ati nǹkan ti o wa ninu ẹ bii ipaya ati àmọ̀dájú, ati ododo ati imọkanga, tabi gbigbero ṣekarimi ati ṣekagbọmi, O si tun maa wo iṣẹ wọn bóyá o dára ni abi ko dára, O maa wa sẹsan lori ẹ.

explain-icon

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  • Ìní akolekan si titun ọkàn ṣe, ati mimọ ọn kuro nibi gbogbo ìròyìn burúkú.
  • Dídára ọkàn pẹ̀lú imọkanga ni, dídára iṣẹ pẹ̀lú itẹle Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ni, àwọn méjèèjì yii ni Ọlọhun maa wò.
  • Ọmọniyan ko gbọdọ gba ẹtan pẹ̀lú dúkìá rẹ tabi ẹwà rẹ tabi ara rẹ, tabi nǹkan kan ninu àwòrán ayé yii.
  • Ikilọ kuro nibi ifayabalẹ lori ìta ti o hàn lai tún inú ti o pamọ ṣe.