explain-icon

Àlàyé

Anabi, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a, n fun wa ni iro pe: Ọlọhun, Onibukun ti O ga julọ sọ pe: Òun ni Olùrọrọ̀ julọ tayọ níní orogún, Òun ni Ẹni tí Ó rọrọ̀ tayọ gbogbo nkan, ati pe ti eniyan bá ṣe iṣẹ ijọsin kan, ti o sì ṣe e fun Ọlọhun ati ohun miiran tó yatọ si Ọlọhun; Ọlọ́hun yoo gbe e ju sílẹ̀, kò nii gbà á lọ́wọ́ rẹ̀, yoo sì dá a padà fún un. Nitori naa, ọranyan ni ki iṣẹ́ jẹ́ mimọ fun Ọlọ́hun Ọba Aleke ọla, nítorí pé, Ọlọ́hun – mimọ fun Un – kò nii gba iṣẹ kan ayafi eyiti ó jẹ́ mimọ lati lè fi ri ojú rere Rẹ̀.

explain-icon

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  • Ìkìlọ̀ kuro nibi ẹbọ pẹlu gbogbo awọn ọna rẹ; ati pe o jẹ ìkọdí fún itẹwọgba iṣẹ ijọsin lọdọ Ọlọhun.
  • Níní ìmọ̀lára ọrọ̀ Ọlọhun ati titobi Rẹ̀, ó wà ninu awọn nkan tó máa n ṣe iranlọwọ lati jẹ ki a ṣe iṣẹ ní mimọ fun Ọlọhun.