Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - n fún wa niroo nipa ìpòfo ati ipadanu awọn onilekoko - laisi ìmọ̀nà ati ìmọ̀ - ninu ẹsin ati igbesi aye wọn, ati ninu awọn ọrọ wọn ati awọn iṣẹ wọn, awọn tí wọ́n máa ń tayọ aala ofin sharia tí Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - mú wá fún wa.