Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – n fun wa ni iro nipa ipo rẹ̀ lọdọ Ọlọhun Ọba, ó n sọ pé ipo naa dé ipo ifẹ tó ga julọ, gẹgẹ bi Anabi Ibrahim – Alaafia fun un – ṣe de bẹ, nitori eyi ni Anabi fi sọ pe òun ò ni ọrẹ aayo kankan yatọ si Ọlọhun; nitori pé ọkàn oun ti kún kẹ́kẹ́ fún ìfẹ́ Ọlọhun Ọba ati gbigbe E tobi àti mímọ̀ ọ́n, nítorí náà kò sí ààyè ninu rẹ̀ fún ẹnikẹ́ni yàtọ̀ sí Ọlọ́hun. Tí ó bá jẹ́ pé ó ní ọ̀rẹ́ aayo ninu àwọn ẹ̀dá ni, ìbá jẹ́ Abu Bakr As-Siddiq, kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i. Lẹyin naa ó ní ka sọra kuro nibi ikọja aala ninu ifẹ, gẹgẹ bi awọn Yahudi ati Nasara ti ṣe sí saare awọn anabi ati awọn ẹni rere inu wọn, titi ti wọn fi sọ wọn di ọlọrun ẹbọ ti wọn n jọsin fun wọn dipo Ọlọhun Allah, ti wọn sì kọ mọṣalaṣi ati ile ijọsin sori awọn saare wọn, Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - kọ̀ fun awọn ijọ rẹ̀ pé wọn kò gbọdọ̀ ṣe gẹgẹ bi awọn Yahudi ati Nasara ṣe ṣe.