Iya awọn olugbagbọ Ummu Salamah- ki Ọlọhun yọnu si i- sọ fun Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- pe dajudaju nigba ti oun fi wa lori ilẹ Habasha, oun ri ṣọọṣi kan- wọn n pe e ni Maariyah- ti awọn aworan ati awọn ẹṣọ ati awọn fọto n bẹ nibẹ; ni ti ìyàlẹ́nu latara ìyẹn! Bayii ni Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ba ṣàlàyé awọn okunfa gbigbe awọn aworan yii síbẹ̀; O sọ pe: Dajudaju awọn ti o dárúkọ wọnyii ti ẹni rere ba ku laaarin wọn, wọn maa kọ mọsalasi kan sori saare rẹ ti wọn ma maa kirun nibẹ, ti wọn si maa ya awọn aworan yẹn, O ṣàlàyé pe dajudaju ẹni ti o ba ṣe yẹn jẹ ẹni ti o buru julọ ninu ẹda lọdọ Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga-; nitori pe iṣe rẹ maa ja si dida orogun pọ mọ Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga-.