Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- kọ kuro nibi ki Musulumi maa sọ nibi ọrọ rẹ pé: "Ti Ọlọhun ba fẹ ati ti lagbaja ba fẹ", Tabi ohun ti Ọlọhun ati lagbaja ba fẹ; Ìyẹn rí bẹ́ẹ̀ nitori pe fifẹ Ọlọhun ati erongba rẹ jẹ nnkan ti a tu kalẹ ti ẹnikẹni ko si ba A kẹgbẹ nibẹ, Ati pe o n bẹ nibi lilo harafi waw nibi asopọ naa, imuninimọlara pe ẹnìkan n ba Ọlọhun kẹgbẹ ati ifidọgba láàrin ẹni yẹn ati Ọlọhun. Ṣugbọn yoo maa sọ pé: Ti Ọlọhun ba fẹ, lẹyin naa ti lagbaja ba fẹ, Ki o fi fifẹ ẹru tẹle fifẹ Ọlọhun pẹlu sisọ pe: "Thummo" dipo "Wa", nitori pe "Thummo" n ṣe àǹfààní ki nǹkan wa lẹyin ati lilọra.