explain-icon

Àlàyé

Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – kọ kuro nibi jijokoo si ori awọn sàréè. Gẹgẹ bi o ṣe kọ kuro nibi kiki irun si awọn sàréè, bii ki sàréè o wa ni agbegbe idojukọ olukirun; nitori pe dajudaju ìyẹn wa ninu awọn atẹgun imu-orogun-mọ Ọlọhun.

explain-icon

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  • Kikọ kuro nibi kiki irun ni itẹ tabi ni aarin rẹ tabi si i lára ayaafi irun oku gẹgẹ bi o ṣe fi ẹsẹ mulẹ ninu sunnah.
  • Kikọ kuro nibi kiki irun si sàréè lati dena ijẹ-atẹgun imu-orogun-mọ Ọlọhun.
  • Isilaamu kọ kuro nibi ikọja ààlà nibi awọn sàréè ati kuro nibi yiyẹpẹrẹ rẹ, ko gbọdọ si àṣejù ko si gbọdọ si aseeto.
  • Ọwọ Musulumi si ṣẹku lẹyin iku rẹ, latari gbolohun rẹ - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – ti o sọ pe: (Rirun eegun oku da gẹgẹ bii rirun un (eegun) ni ààyè ni).