explain-icon

Àlàyé

Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - n kọ̀ fun wa kuro nibi ìyinnijù ati ikọja aala ofin sharia nibi yiyin-in ati riroyin rẹ̀ pẹlu awọn iroyin Ọlọhun Ọba ati awọn iṣẹ tó jẹ́ ti Ọlọhun nikan ṣoṣo, tabi kí a sọ pé Anabi ní imọ kọ̀kọ̀, tabi ki a maa pe e papọ mọ Ọlọhun, gẹgẹ bi awọn Kristẹni ṣe ṣe pẹlu Isa ọmọ Maria - ki alaafia Ọlọhun maa ba a. Lẹyin naa, Anabi ṣalaye pé ẹru kan ninu awọn ẹru Ọlọhun ni oun, ó sì paṣẹ pé ki a maa sọ nipa oun bayii pé: Ẹru Ọlọhun ati Ojiṣẹ Rẹ̀.

explain-icon

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  • Iṣọnilara kuro nibi titayọ aala ofin sharia nibi ẹyìn; nitori pe ó máa n ja si ẹbọ ni.
  • Ohun ti Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - n kilọ fun wa nipa rẹ̀, ó ti ṣẹlẹ ninu ijọ yii, nitori awọn ẹgbẹ kan ti tayọ aala lara Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - awọn ẹgbẹ kan sì tayọ aala lara awọn ara ile Anabi, awọn ẹgbẹ kan tún tayọ aala lara awọn wòlíì Ọlọhun, gbogbo wọn bá kó sinu ẹbọ.
  • Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - royin ara rẹ̀ pé ẹru Ọlọhun ni oun; nitori kí ó lè fi hàn pé dajudaju ẹru ti Allah ń rè ni oun, nitori naa kò lẹtọọ ki a dari nkankan ninu awọn ìròyìn ẹ̀ṣà Oluwa si ọdọ rẹ̀.
  • Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - royin ara rẹ̀ pé ojiṣẹ Ọlọhun ni oun; nitori kí ó lè fi hàn pé dajudaju ojiṣẹ kan lati ọdọ Ọlọhun ni oun, nitori naa ọranyan ni ki a pe e lódodo ki a si tẹle e.