Arakunrin kan wa si ọdọ Anabi, o si ba a sọro nipa ọrọ ara rẹ, lẹ́yìn naa o sọ pe: “Ohunkohun ti Ọlọhun ba fẹ ati ohunkohun ti o ba fẹ”, Ojiṣẹ Ọlọhun, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a, bá tako ọrọ yii o si sọ fun un pe sise idapọ fifẹ ẹda pẹ̀lú fifẹ Ọlohun pẹlu lẹ́tà “waw” jẹ ìsẹbọ kekere si Ọlọhun, ko si lẹtọọ fun Musulumi lati sọ ọ, Lẹ́yìn náà, ó ṣamọ̀nà rẹ̀ sí ọ̀rọ̀ òtítọ́ náà pé: “Ohunkóhun tí Ọlọ́hun nìkan ṣoṣo ba fẹ́,” nítorí náà ó maa ya Ọlọ́hun sọ́tọ̀ nínú ìfẹ́ Rẹ̀, kò sì nii so fifẹ ẹni kankan mọ ọn pẹlu èyíkéyìí ninu iran asopọ.