Awọn ikọ kan wa ba Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a -, ti onka wọn sì jẹ mẹwaa, ti o si gba ọwọ adehun (ibura) mẹsan ninu wọn lori Isilaamu ati itẹle aṣẹ, ti ko si gba ọwọ adehun (ibura) ti ẹni kẹwàá, nigba ti wọn wa beere nipa idi ìyẹn o sọ - ki ikẹ ati ọla maa ba a - pe: Dajudaju agbekọ n bẹ lara rẹ, oun naa ni nkan ti wọn maa n de tabi ti wọn maa n sokọ latara ilẹkẹ ati nkan miran yatọ si i lati fi ti ojukoju tabi inira danu. Ni arakunrin naa wa ti ọwọ rẹ bọ aaye ti agbekọ naa wa ti o si ja a ti o si bọra kuro nibẹ, nigba naa ni o gba ọwọ adehun pẹlu Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a -, o (Anabi) wa sọ lẹni ti n kilọ kuro nibi agbekọ ti o si n ṣe alaye idajọ rẹ pe: Ẹni ti o ba so agbekọ ó ti ṣe ẹbọ (mu orogun mọ Ọlọhun)”