Wọn bi Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – leere nipa awọn ti wọn maa n sọ nipa awọn kọkọ ti yio ṣẹlẹ ni ọjọ iwaju, ni o wa sọ pe: Ẹ ma bikita pẹlu wọn, Ẹ si ma di ọrọ wọn mu, alamọri wọn o si gbọdọ pataki si yin. Ni wọn wa sọ pe: Dajudaju ọrọ wọn maa n ṣe deedee nkan ti n ṣẹlẹ ni igba miran, gẹgẹ bii ti wọn ba sọ nipa iṣẹlẹ alamọri kọkọ kan ni oṣu bayii ni ọjọ bayii, ti yio si ṣẹlẹ ni ibamu si ọrọ wọn. Ni o wa sọ - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – pe: Dajudaju awọn alujannu maa n ji awọn iroyin sanmọ gbọ, nigba naa ni wọn yio wa sọkalẹ wa ba awọn aayo wọn ninu awọn adagbigba ti wọn o si fun wọn ni iro nkan ti wọn gbọ, lẹ́yìn naa ni adagbigba o fi irọ ọgọrun-un kun eyi ti o gbọ lati sanmọ.