explain-icon

Àlàyé

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣàlàyé ọla ti o n bẹ fun irun ti a ki ni mọsalasi rẹ, pe o lọla ni ẹsan ju ẹgbẹrun irun ti a ki lọ ni ibi ti o yatọ si i ninu awọn mọsalasi aye, afi irun ti a ba ki ni mọsalasi ọwọ ni Makkah, oun lọla ju irun ti a ki ni mọsalasi rẹ- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- lọ.

explain-icon

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  • Adipele ẹsan fun irun ti a ba ki ni mọsalasi abeewọ, ati ni mọsalasi ti Anabi.
  • Irun ti a ba ki ni mọsalasi abeewọ loore ju ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún irun ti a ki ni eyi ti o yatọ si i ninu awọn mọsalasi lọ.