explain-icon

Àlàyé

Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – tọka awọn ijọ rẹ sibi adua ti wọn maa ṣe nigba ti wọn ba fẹ wọ masalaasi: (Allāhummo iftah li abwaaba rahmotika), nigba naa ni yio beere lọwọ Ọlọhun ti ọla Rẹ ga ki O ṣe ni irọrun fun un awọn okunfa ikẹ Rẹ, ati pe ti o ba fẹ jade ki o sọ pe: (Allāhummo inni as’aluka min fadlika), nigba naa yio waa bẹ Ọlọhun ninu ọla Rẹ ati alekun daadaa Rẹ ninu jijẹ-mimu halaali.

explain-icon

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  • A fẹ ki a ṣe adua yii nigba ti a ba fẹ wọ masalaasi ati nigba ti a ba fẹ jade kuro nibẹ.
  • Sisẹsa didarukọ ikẹ nigba ti a ba fẹ wọle, ati ọla nigba ti a ba fẹ jade: Dajudaju ẹni ti o n wọle ko airoju pẹlu nkan ti yio sun un mọ Ọlọhun ati alujanna, nitori naa o ṣe deedee ki o darukọ ikẹ, ati pe nigba ti o ba jade yio kaakiri ori ilẹ lati wa ọla Ọlọhun ninu jijẹ-mimu lọ, nitori naa o ṣe deedee ki o darukọ ọla.
  • Awọn asikiri yii a maa n sọ wọn nigba ti a ba gbero lati wọ masalaasi, ati nigba ti a ba gbero lati jade kúrò nibẹ.