Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe dajudaju nini ifẹ awọn Ansar ninu awọn ara Madina, jẹ àmì lori pipe igbagbọ; eleyii rí bẹ́ẹ̀ nitori gbigba iwaju wọn nibi aranṣe Isilaamu ati Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-, ati gbigbiyanju nibi gbigba awọn Musulumi sile, ati nina awọn dukia wọn ati ẹmi wọn si oju ọna Ọlọhun, ati pe kikorira wọn jẹ ami lori ṣiṣe sobẹ-ṣelu. Lẹyin naa, Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣàlàyé pe dajudaju ẹni ti o ba nífẹ̀ẹ́ awọn Ansar, Ọlọhun maa nifẹẹ rẹ, ẹni ti o ba si korira wọn Ọlọhun maa korira rẹ.