Anabi, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a, sọ pe oun yoo wa nibi odò adágún rẹ ni ọjọ igbende láti ri awọn ti wọn maa wa síbẹ̀ nínú ìjọ rẹ, Wọn maa mu awọn èèyàn kan kúrò ni tòsí ọdọ rẹ, ki ikẹ ati ọla maa ba a, o maa wa sọ pé: Irẹ Oluwa mi, ara mi ni wọn, ara ìjọ mi si ni wọn, Wọn maa sọ pé: Ǹjẹ́ o mọ ohun tí wọn ṣe lẹ́yìn ti ẹ ti jọ pínyà, mo fi Ọlọhun bura, wọ́n kò yẹ̀ wọn kò gbò ti wọn n kúrò nínú ẹsin wọn, wọn kì í ṣe ara rẹ, wọn o si ki i ṣe ara ìjọ rẹ.