Nigba ti ayah sọkalẹ: (Thumma latus alunna yauma-izin ‘anin na’eem) o n túmọ̀ si pe: Wọn maa pada beere lọwọ wọn nipa idupẹ lori nnkan ti Ọlọhun ṣe ni idẹra le wọn lori ninu awọn idẹra, Az-Zubair ọmọ Al-‘Awwam- ki Ọlọhun yọnu si i- sọ pe: Irẹ Ojiṣẹ Ọlọhun, idẹra wo ni wọn maa bi wa leere nipa rẹ? Dajudaju idẹra mejeeji ko kii ṣe nnkan ti wọn le bukaata si ibeere ati pe mejeeji ni eso dabinu ati omi! Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe: Dajudaju wọn maa bi yin leere nipa idẹra pẹlu isẹsi yii ti ẹ wa nibẹ yìí, nitori pe mejeeji jẹ idẹra nla meji ninu awọn idẹra Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga-.