Awọn ọkunrin kan ninu awọn ẹlẹbọ (awọn ti wọn n mu nkan mii mọ Ọlọhun) wa ba Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a -, wọn si ti pa eeyan lọpọlọpọ ti wọn ti ṣe ọpọlọpọ agbere, ni wọn wa sọ fun Anabi pe: Dajudaju nkan ti o n pepe si ninu Isilaamu ati awọn ẹkọ rẹ nkan ti o daa ni, ṣugbọn bawo ni ọrọ wa o ṣe wa jẹ pẹlu nkan ti a ti ko si ni imu orogun mọ Ọlọhun ati awọn ẹṣẹ nlanla, njẹ ìpẹ̀ṣẹ̀rẹ́ wa fun un bi? Nitori naa ni aaya mejeeji yii ba sọkalẹ, nibi ti Ọlọhun ti gba ironupiwada lọwọ awọn eeyan pẹlu pipọ awọn ẹṣẹ wọn ati titobi rẹ, ati pe bi ko ba ṣe titori iyẹn wọn o ba si wa lori ṣiṣe keferi wọn ati àgbéré wọn, wọn ba si ma wọ inu ẹsin yii.