Nigba ti Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - rán muaz ọmọ Jabal - ki Ọlọhun yọnu si i - lọ sí ilu Yemen lati lọ kéde ẹ̀sìn Ọlọhun fún wọn, kí ó sì kọ́ wọn ní ìmọ̀ ẹ̀sìn Islam, ó ṣalaye fun un pé dajudaju ó máa ṣalabapade awọn ọmọ Kristẹni kan nibẹ; nitori naa, ki o gbaradi fun wọn, lẹyin naa, ki o bẹrẹ ikede ẹsin Islam fun wọn pẹlu sísọ nkan tó pataki julọ, lẹyin naa ki o wá sọ nkan tó pataki tèlé e, Kí ó kọ́kọ́ pè wọ́n lọ síbi ṣiṣatunṣe igbagbọ wọn; iyẹn ni pé kí wọ́n jẹrii pé dajudaju kò sí ọlọhun miran ayafi Ọlọhun Allah, ati pé dajudaju Anabi Muhammad Ojiṣẹ Ọlọhun ní n ṣe; Nítorí pé eyi ni ó máa mú wọn wọ inu ẹsin Islam, tí wọ́n bá ti gbà lati ṣe iyẹn, kí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ waa pa wọ́n laṣẹ pé kí wọ́n maa gbé ìrun duro; nitori pe irun ni iṣẹ ọranyan tí ó tóbi jùlọ lẹyin tí a bá ti ṣe Ọlọhun lọ́kan, tí wọ́n bá gbé irun naa duro, kí o pa àwọn olówó inu wọn láṣẹ pé kí wọ́n yọ zakat owó wọn fún àwọn tálákà inu wọn, lẹ́yìn náà, Anabi ṣe ìkìlọ̀ fún Muaz pé kó má ṣe gba owó tó níye lórí jù lọ; nitori pe eyi tó jẹ́ ọranyan ni eyi tó wà ní iwọntun-wọnsì lẹyin naa, ó tún gbà á nímọ̀ràn pé kó jìnà sí àbòsí; nitori ki ẹni tí ó bá ṣabosi sí má baa ṣepe fun un, nitori pé dajudaju adura rẹ̀ maa gbà.