Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ṣe alaye pe dajudaju o jẹ dandan ki ìṣesí awọn Musulumi pẹlu ara wọn o maa jẹ nibi nini ifẹ daadaa ati ikẹ ati ikunlọwọ ati aranṣe, ati titara pẹlu nkan ti o ba ṣẹlẹ si wọn ni inira, gẹgẹ bii ara kan soso, nigba ti oríkèé kan ninu rẹ ba ṣe aisan, gbogbo ara ni yio ba a ṣe papọ nibi aisun ati igbona.