Anas ọmọ Maalik- ki Ọlọhun yọnu si i- n sọ pé: Nígbà tí àwọn saabe jókòó pẹ̀lú Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- nínú mọṣalaaṣi, ni ọkùnrin kan ba wọlé lórí ràkúnmí, o wa da a gunlẹ, lẹ́yìn náà o si dè é, Lẹ́yìn naa o bi wọn leere pé: Ewo ninu yin ni Muhammad? Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- rọgbọku láàrin àwọn èèyàn, ni a wa sọ pé: Ọkunrin pupa ti o rọgbọku yii ni, Ọkunrin naa sọ fun un pe: Iwọ ọmọ Abdul Muttalib, Ni Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa sọ fún un pé: Mo gbọ́ ẹ, bèèrè, maa da ẹ lóhùn. Arákùnrin naa wa sọ fún Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- pé: Dajudaju èmi maa bi ọ léèrè, mo si maa le mọ́ ọ nibi ibeere naa, ma ṣe binu si mi. Ìtumọ̀ ni pé: Ma bínú si mi, ma si jẹ ki ipọnju ba ọ, O sọ pé: Beere ohun ti o fẹ, O wa sọ pe: Mo n fi Olúwa rẹ àti Olúwa àwọn ti wọn ṣáájú rẹ bẹ̀ ọ́, ǹjẹ́ Ọlọhun ni O ran ọ si awọn èèyàn? O sọ pé: Bẹẹni, lati fi kanpá mọ́ òdodo rẹ, Ọkùnrin náà sọ pé: ANSHUDUKA BILLAAH, itumọ rẹ ni pé: Mo n fi Ọlọhun bẹ ọ, ǹjẹ́ Ọlọhun ni O pa ọ láṣẹ ki a maa ki ìrun wákàtí márùn-ún ni ojúmọ́? Àwọn náà ni àwọn irun ọran-anyan, O sọ pe: Beeni, O sọ pe: Mo n fi Ọlọhun bẹ ọ, njẹ Ọlọhun ni O pa ọ láṣẹ ki a maa gba aawẹ oṣù yìí ninu ọdún? Ìtumọ̀ rẹ ni: Oṣù Ramadan, O sọ pé: Bẹẹni, O sọ pe: Mo n fi Ọlọhun bẹ ọ, ǹjẹ́ Ọlọhun ni O pa ọ láṣẹ ki o gba sàráà yii lọ́wọ́ awọn olowo wa ki o si pin in fun awọn talika wa? Oun naa ni sàká, Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa sọ pé: Bẹẹni, Dimaam wa gba Isilaamu, o wa sọ fun Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- pé oun maa pe ìjọ oun sinu Isilaamu. Lẹ́yìn náà ni o wa ṣe àfihàn ara rẹ pé oun ni Dimaam ọmọ Tha’labah lati ìdílé Banuu Sahd ọmọ Bakr.