explain-icon

Àlàyé

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n ṣàlàyé ọla ti o n bẹ fun wiwọ inu Isilaamu, Ati pe dajudaju ẹni ti o ba gba Isilaamu ti Isilaamu rẹ si daa ti o si jẹ olumọkanga olododo; wọn ko nii ṣe ìṣirò ìṣẹ́ nnkan ti o ba ṣe ni asiko aimọkan ninu awọn ẹṣẹ, Ati pe ẹni ti o ba ṣe aburu ninu Isilaamu pẹ̀lú ki o jẹ ṣọbẹ-ṣelu tabi ki o ṣẹri pada kuro nibi ẹsin rẹ; wọn maa ṣe ìṣirò ìṣẹ́ nnkan ti o ṣe ninu aigbagbọ ati nnkan ti o ṣe ninu Isilaamu.

explain-icon

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  • Àkólékàn awọn Sọhaba- ki iyọnu Ọlọhun maa ba wọn- ati ipaya wọn ninu nnkan ti o n bẹ fun wọn ninu awọn iṣẹ ti wọn ṣe ni asiko aimọkan.
  • Isẹnilojukokoro lori iduroṣinṣin lori Isilaamu.
  • Ọla ti o n bẹ fun wiwọ inu Isilaamu ati pe dajudaju o maa n pa awọn iṣẹ ìṣáájú rẹ́ ni.
  • Ẹni ti ko ṣe Isilaamu mọ ati ṣọbẹ- ṣelu, wọn yoo ṣe ìṣirò gbogbo iṣẹ́ kọọkan fun un eyi ti o ṣáájú ni asiko aimọkan, ati gbogbo ẹṣẹ kọọkan ti o ṣe ninu Isilaamu.